Isaiah 5:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn, ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú, òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn enia mi lọ si oko-ẹrú, nitoriti oye kò si, awọn ọlọla wọn di rirù, ati ọ̀pọlọpọ wọn gbẹ fun orùngbẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò lọ sí ìgbèkùn nítorí òye kò sí fún wọn, ebi ni yóò pa àwọn bọ̀rọ̀kìnní wọn kú; ẹgbàágbèje wọn ni òrùgbẹ yóò sì gbẹ.