Isaiah 5:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì, ó ti yanu kalẹ̀. Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́, ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú, ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ipò-òkú ti fun ara rẹ̀ li àye, o si là ẹnu rẹ̀ li aini ìwọn: ati ogo wọn, ati ọ̀pọlọpọ wọn, ati ọṣọ́ wọn, ati awọn ẹniti nyọ̀, yio sọkalẹ sinu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi, ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada, nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.