Isaiah 5:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó kọ́ ilẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣa gbogbo òkúta ibẹ̀ kúrò. Ó gbin àjàrà dáradára sinu rẹ̀. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ gíga sí ààrin rẹ̀, ó sì ṣe ibi tí wọn yóo ti máa fún ọtí sibẹ. Ó ń retí kí àjàrà rẹ̀ so, ṣugbọn èso kíkan ni ó so.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si sọ ọ̀gba yi i ka, o si ṣà okuta kuro ninu rẹ̀, o si gbìn ayànfẹ àjara si inu rẹ̀, o si kọ ile iṣọ sãrin rẹ̀, o si ṣe ifunti sinu rẹ̀ pẹlu: o si wò pe ki o so eso, ṣugbọn eso kikan li o so.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà síi. Ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí inú un rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan ṣíbẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọn èṣo búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.