Isaiah 5:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n, àwọn òkè sì mì tìtì. Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro, sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni ibinu Oluwa fi ràn si enia rẹ̀, o si ti na ọwọ́ rẹ̀ si wọn, o si ti lù wọn: awọn òke si warìri, okú wọn si wà bi igbẹ li ãrin igboro. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ìbínú OLÚWA gbóná mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ ṣókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀. Àwọn òkè mì tìtì, àwọn òkú sì dàbí ààtàn lójú òpópó ọ̀nà. Pẹ̀lúu gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíí kúrò, ọ̀wọ́ rẹ̀ sì gbé ṣókè síbẹ̀.