Isaiah 5:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn óo hó lé Israẹli lórí lọ́jọ́ náà bí ìgbà tí omi òkun ń hó. Bí eniyan bá wọ ilẹ̀ náà yóo rí òkùnkùn ati ìnira. Ìkùukùu rẹ̀ yóo sì bo ìmọ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọjọ na nwọn o ho si wọn, bi hiho okun: bi ẹnikan ba si wo ilẹ na, kiyesi i, okùnkun ati ipọnju, imọlẹ si di okùnkun ninu awọsanma dudu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí gẹ́gẹ́ bí i rírú omi òkun. Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀, yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́; pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kùrukùru rẹ̀.