Isaiah 5:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo jẹ́ kí ó di igbó, ẹnikẹ́ni kò ní ro ó mọ́, wọn kò sì ní tọ́jú rẹ̀ mọ́. Ẹ̀gún ati ẹ̀wọ̀n agogo ni yóo hù níbẹ̀. N óo pàṣẹ fún òjò kí ó má rọ̀ sórí rẹ̀ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si sọ ọ di ahoro, a kì yio tọ́ ẹka rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio wà a, ṣugbọn ẹ̀wọn ati ẹ̀gún ni yio ma hù nibẹ, emi o si paṣẹ fun awọsanma ki o má rọjò sori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro láì kọ ọ́ láì rò ó, ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀. Èmi yóò sì pàṣẹ fún kùrukùru láti má ṣe rọ̀jò sóríi rẹ̀.”