Isaiah 5:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ilé Israẹli ni ọgbà àjàrà OLUWA ọmọ ogun, àwọn ará Juda ni àjàrà dáradára tí ó gbìn sinu rẹ̀. Ó ń retí kí wọn máa ṣe ẹ̀tọ́, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń paniyan; ó ń retí ìwà òdodo, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọn ń ni lára ni wọ́n ń kígbe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọ̀gba àjara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ile Israeli, ati awọn ọkunrin Juda ni igi-gbìgbin ti o wù u, o reti idajọ, ṣugbọn kiyesi i, inilara; o si reti ododo; ṣugbọn kiyesi i, igbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọgbà-àjàrà OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni ilé Ísírẹ́lì àwọn ọkùnrin Júdà sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọn, ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni ó rí, Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ ẹkún ìpayínkeke.