Isaiah 50:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: OLUWA ní: “Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà? Ta ni mo tà yín fún, tí mo jẹ lówó? Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín, nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BAYI ni Oluwa wi, Nibo ni iwe ikọsilẹ iyá nyin gbe wà, ẹniti mo ti kọ̀ silẹ? tabi tani ninu awọn onigbese mi ti mo ti tà nyin fun? Kiyesi i, nitori aiṣedẽde nyin li ẹnyin ti tà ara nyin, ati nitori irekọja nyin li a ṣe kọ̀ iyá nyin silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA wí níyìí: “Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà èyí tí mo fi lé e lọ? Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi ni mo tà ọ́ fún? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́; nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.