Isaiah 50:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná, tí ẹ tan iná yí ara yín ká, ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá; ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín. Ẹ óo wà ninu ìrora.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiye si i, gbogbo ẹnyin ti o dá iná, ti ẹ fi ẹta iná yi ara nyin ká: ẹ mã rìn ninu imọlẹ iná nyin, ati ninu ẹta iná ti ẹ ti dá. Eyi ni yio jẹ ti nyin lati ọwọ́ mi wá; ẹnyin o dubulẹ ninu irora.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná tí ẹ sì ń pèṣè iná ìléwọ́ fún ara yín, ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín àti ti ìtùfú tí ẹ ti kánná lù. Ohun tí ẹ ó gbà lọ́wọ́ mi nìyìí: Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìpọ́njú.