Isaiah 50:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan; mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn? Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni; àbí n kò lágbára láti gba ni là? Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun, tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀, omi wọn gbẹ, òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa, wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori nigbati mo de, kò si ẹnikan? nigbati mo pè, kò si ẹnikan lati dahùn? Ọwọ́ mi ha kuru tobẹ̃ ti kò fi le rapada? tabi emi kò ha li agbara lati gbani? Kiyesi i, ni ibawi mi mo gbẹ okun, mo sọ odò nla di aginjù, ẹja wọn nrùn nitori ti omi kò si, nwọn si kú fun ongbẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan? Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn? Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́? Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí? Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun, Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀; àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi wọ́n sì kú fún òùngbẹ.