Isaiah 50:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu. Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú. Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀, kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa Jehofa ti fi ahọn akẹ́kọ fun mi, ki emi ki o le mọ̀ bi a iti sọ̀rọ li akokò fun alãrẹ, o nji li oròwurọ̀, o ṣi mi li eti lati gbọ́ bi akẹkọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.