Isaiah 50:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba; mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu. N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo fi ẹ̀hìn mi fun awọn aluni, ati ẹ̀rẹkẹ mi fun awọn ti ntú irun: emi kò pa oju mi mọ́ kuro ninu itìju ati itutọ́ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irúngbọ̀n mi; Èmi kò fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọsùtì sí.