Isaiah 51:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá, pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni. Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí, wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn; ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹni ìràpadà OLÚWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Ṣíhónì wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo oríi wọn. Ayọ̀ àti inú-dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.