Isaiah 51:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ, tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ, tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára, nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run? Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti iwọ si gbagbe Oluwa Elẹda rẹ ti o ti nà awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; ti iwọ si ti mbẹ̀ru nigbagbogbo lojojumọ nitori irúnu aninilara nì, bi ẹnipe o ti mura lati panirun? nibo ni irúnu aninilara na ha gbe wà?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
tí ìwọ sì gbàgbé OLÚWA ẹlẹ́dàá rẹ, ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́ nítorí ìbínú àwọn aninilára, tí wọ́n sì gbọ́kàn lé ipanirun? Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?