Isaiah 51:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àárẹ̀ mú àwọn ọmọ rẹ, wọ́n sùn káàkiri ní gbogbo òpópó, bí ìgalà tí ó bọ́ sinu àwọ̀n. Ibinu OLUWA rọ̀jò lé wọn lórí, àní ìbáwí Ọlọrun rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti dáku, nwọn dubulẹ ni gbogbo ikorita, bi ẹfọ̀n ninu àwọn: nwọn kún fun ìrúnu Oluwa, ibawi Ọlọrun rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú; wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí ẹtu tí a dé mọ́nú àwọ̀n. Ìbínú OLÚWA ti kún inú un wọn fọ́fọ́ọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín.