Isaiah 51:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oluwa rẹ, àní OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní, “Wò ó! Mo ti gba ife àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lọ́wọ́ rẹ, O kò ní rí ibinu mi mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni Oluwa rẹ Jehofa wi, ati Ọlọrun rẹ ti ngbèja enia rẹ̀, Kiyesi i, emi ti gbà ago ìwárìri kuro lọwọ rẹ, gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago irúnu mi; iwọ kì yio si mu u mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí OLÚWA yín Alágbára jùlọ wí nìyìí, Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn an rẹ̀ mọ́ “Kíyèsí i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ọ̀ rẹ kọ́ọ̀bù tí ó mú ọ ta gbọ̀ngbọ̀nọ́n; láti inú kọ́ọ̀bù náà, ẹ̀kan ìbínú mi, ni ìwọ kì yóò mu mọ́.