Isaiah 51:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí ń dá ọ lóró ni yóo rí ibinu mi, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí á gba orí rẹ kọjá;’ tí wọ́n sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀ẹ́lẹ̀, tí wọ́n sọ ọ́ di ojú ọ̀nà wọn, tí wọn óo máa gbà kọjá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o fi i si ọwọ́ awọn ti o pọ́n ọ loju; ti nwọn ti wi fun ọkàn rẹ pe, Wólẹ, ki a ba le rekọja: iwọ si ti tẹ́ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi ita, fun awọn ti o rekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nnílójú rẹ lọ́wọ́, àwọn tí ó wí fún ọ pé, ‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lóríì rẹ.’ Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lóríi rẹ̀.”