Isaiah 51:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“OLUWA yóo tu Sioni ninu, yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu; yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA. Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀, pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Oluwa yio tù Sioni ninu; yio tú gbogbo ibi ofo rẹ̀ ninu; yio si ṣe aginju rẹ̀ bi Edeni, ati aṣálẹ rẹ̀ bi ọgbà Oluwa, ayọ̀ ati inudidùn li a o ri ninu rẹ̀, idupẹ, ati ohùn orin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dájúdájú, OLÚWA yóò tu Ṣíhónì nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Ídẹ́nì, gbogbo ìgbòrò rẹ̀ yóò rí bí ọgbà OLÚWA. Ayọ̀ àti inúdídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.