Isaiah 51:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin eniyan mi, ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, òfin kan yóo ti ọ̀dọ̀ mi jáde, ìdájọ́ òdodo mi yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tẹtilelẹ si mi, ẹnyin enia mi; si fi eti si mi, iwọ orilẹ-ède mi: nitori ofin kan yio ti ọdọ mi jade lọ, emi o si gbe idajọ mi kalẹ fun imọlẹ awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Tẹ́tí sími, ẹ̀yin ènìyàn mi; gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀ èdè mi: Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá; ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀ èdè.