Isaiah 51:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ, kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú; ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae, ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kòkoro yio jẹ wọn bi ẹ̀wu, idin yio si jẹ wọn bi irun agutan: ṣugbọn ododo mi yio wà titi lai, ati igbala mi lati iran de iran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ; Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí Ẹ̀gbọ̀n òwú. Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé, àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”