Isaiah 52:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jí, Sioni, jí! Gbé agbára rẹ wọ̀ bí aṣọ, gbé ẹwà rẹ wọ̀ bí ẹ̀wù, ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́; nítorí àwọn aláìkọlà ati aláìmọ́, kò ní wọ inú rẹ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
JI! ji! gbe agbara rẹ wọ̀, iwọ Sioni; gbe aṣọ ogo rẹ wọ̀, iwọ Jerusalemu, ilu mimọ́: nitori lati igbayi lọ, alaikọla on alaimọ́ kì yio wọ̀ inu rẹ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jí, jí, Ìwọ Ṣíhónì, wọ ara rẹ ní agbára. Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀, Ìwọ Jérúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ n nì. Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́ kì yóò wọ inú un rẹ mọ́.