Isaiah 52:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu, nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀, òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni yio buwọ́n ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède; awọn ọba yio pa ẹnu wọn mọ si i, nitori eyi ti a kò ti sọ fun wọn ni nwọn o ri; ati eyi ti nwọn kò ti gbọ́ ni nwọn o rò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀ èdè ká, àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítoríi rẹ̀. Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i, àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.