Isaiah 52:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, Oluwa wipe, Kini mo nṣe nihin, ti a kó awọn enia mi lọ lọfẹ? awọn ti o jọba wọn mu nwọn kigbe, li Oluwa wi; titi lojojumọ li a si nsọ̀rọ odì si orukọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni OLÚWA wí. “Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn tí ó sì ń jọba lé wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,” ni OLÚWA wí. “Àti ní ọjọọjọ́ orúkọ mi ni a ṣọ̀rọ̀ òdì sí nígbà gbogbo.