Isaiah 52:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awọn enia mi yio mọ̀ orukọ mi li ọjọ na: nitori emi li ẹniti nsọrọ: kiyesi i, emi ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi; nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni ó ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”