Isaiah 52:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ jọ máa kọrin pọ̀, gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀, nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu, yóo ra Jerusalẹmu pada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bú si ayọ̀, ẹ jumọ kọrin, ẹnyin ibi ahoro Jerusalemu: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, o ti rà Jerusalemu pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀, ẹ̀yin ahoro Jérúsálẹ́mù, nítorí OLÚWA ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jérúsálẹ́mù padà.