Isaiah 53:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín, láàrin àwọn eniyan ńlá, yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun, nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú, wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina emi o fun u ni ipín pẹlu awọn ẹni-nla, yio si ba awọn alagbara pín ikogun, nitori o ti tú ẹmi rẹ̀ jade si ikú: a si kà a mọ awọn alarekọja, o si rù ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ; o si nṣipẹ̀ fun awọn alarekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀míi rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárèékọjá Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárèékọjá.