Isaiah 53:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa, wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa; ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia, nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n a ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedédé wa a pa á lára nítorí àìsòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lóríi rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi múwa láradá.