Isaiah 53:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú, sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀, wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa, ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A jẹ ẹ ni iyà, a si pọ́n ọ loju, ṣugbọn on kò yà ẹnu rẹ̀: a mu u wá bi ọdọ-agutan fun pipa, ati bi agutan ti o yadi niwaju olurẹ́run rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A jẹ ẹ́ níyà, a sì pọ́n ọn lójú, ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.