Isaiah 54:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Máa kọrin! Ìwọ àgàn tí kò bímọ. Máa kọrin sókè, ìwọ tí kò rọbí rí. Nítorí ọmọ ẹni tí ọkọ ṣátì pọ̀, ju ọmọ ẹni tí ń gbé ilé ọkọ lọ, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
KỌRIN, iwọ àgan, ti kò bi ri; bú si orin, si ké rara, iwọ ti kò rọbi ri; nitori awọn ọmọ ẹni-alahoro pọ̀ ju awọn ọmọ ẹniti a gbe ni iyawo: li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kọrin, Ìwọ obìnrin àgàn, ìwọ tí kò tí ì bímọ rí; búsí orin, ẹ hó fún ayọ̀, ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí; nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,” ni OLÚWA wí.