Isaiah 54:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣí kúrò, tí a sì ṣí àwọn òkè kéékèèké nídìí, ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀, kò ní yẹ̀ lára rẹ, majẹmu alaafia mi tí mo bá ọ dá kò ní yẹ̀. Èmi OLUWA tí mo ṣàánú fún ọ ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awọn oke-nla yio ṣi lọ, a o si ṣi awọn oke kékèké ni idi, ṣugbọn ore mi kì yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni emi kì yio ṣi majẹmu alafia mi ni ipò: li Oluwa wi, ti o ṣãnu fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá tí a sì sí àwọn òkè kékeré nídìí, Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,” ni OLÚWA, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.