Isaiah 54:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ, tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná, tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀, èmi náà ni mo dá apanirun, pé kí ó máa panirun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiye si i, emi li ẹniti o ti dá alagbẹ̀dẹ ti nfẹ́ iná ẹyín, ti o si mu ohun-elò jade fun iṣẹ rẹ̀; emi li o si ti dá apanirun lati panirun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kíyèsí i, Èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ tí ń fẹ́ iná èédú di èjò-iná tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu. Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;