Isaiah 54:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jà tí yóo lágbára lórí rẹ. Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́, ni o óo jàre wọn. Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA, ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si ohun-ijà ti a ṣe si ọ ti yio lè ṣe nkan; ati gbogbo ahọn ti o dide si ọ ni idajọ ni iwọ o da li ẹbi. Eyi ni ogún awọn iranṣẹ Oluwa, lati ọdọ mi ni ododo wọn ti wá, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò ṣe nǹkan, ìwọ yóò já ahọ́nkáhọ́n tó bá fẹ̀ṣùn kàn ọ́ kulẹ̀. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ OLÚWA, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni OLÚWA wí.

Recommended Reading