Isaiah 54:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ, Ọlọrun gbogbo ayé ni à ń pè é.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Ẹlẹda rẹ li ọkọ rẹ; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀; ati Olurapada rẹ Ẹni-Mimọ Israeli; Ọlọrun agbaiye li a o ma pè e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Ẹlẹ́dáà rẹ ni ọkọ rẹ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ni Olùràpadà rẹ; a sì pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.