Isaiah 54:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ìgbà ayé Noa ni Ọ̀rọ̀ yìí rí sí mi: mo búra nígbà náà, pé omi Noa kò ní bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra nisinsinyii, pé n kò ní bínú sí ọ mọ́, pé n kò ní bá ọ wí mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi awọn omi Noa li eyi ri si mi, nitori gẹgẹ bi mo ti bura pe omi Noa kì yio bò aiye mọ, bẹ̃ni mo si ti bura pe emi kì yio binu si ọ, bẹ̃ni emi kì yio ba ọ wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Núà, nígbà tí mo búra pé àwọn omi Núà kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìnyìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.