Isaiah 55:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa jáde ní Babiloni, alaafia ni wọ́n óo fi máa sìn yín sọ́nà, òkè ńlá ati kéékèèké yóo máa kọrin níwájú yín. Gbogbo igi inú igbó yóo sì máa pàtẹ́wọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ayọ̀ li ẹ o fi jade, alafia li a o fi tọ́ nyin: awọn oke-nla ati awọn oke kékèké yio bú si orin niwaju nyin, gbogbo igi igbẹ́ yio si ṣapẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀ a ó sì daríi yín lọ ní àlàáfíà; òkè ńlá ńlá àti kéékèèkéé yóò bú sí orin níwájúu yín àti gbogbo igi inú un pápá yóò máa pàtẹ́wọ́.