Isaiah 56:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹli gbogbo wọn kò mọ nǹkankan. Ajá tí ó yadi ni wọ́n, wọn kò lè gbó; oorun ni wọ́n fẹ́ràn. Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Afọju li awọn alore rẹ̀: òpe ni gbogbo wọn, odi ajá ni nwọn, nwọn kò le igbó, nwọn a ma sùn, nwọn ndubulẹ, nwọn fẹ ma tõgbé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn olùṣọ́ Ísírẹ́lì fọ́jú, gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀; Gbogbo wọn jẹ́ adití ajá, wọn kò lè gbó; wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá, wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.