Isaiah 56:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì, wọn kì í yó. Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan. Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn, olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ ọjẹun aja ni nwọn ti kì iyó, ati oluṣọ́ agutan ti kò moye ni nwọn: olukuluku wọn nwò ọ̀na ara wọn, olukuluku ntọju ere rẹ̀ lati ẹ̀kun rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀; wọn kì í ní ànító. Wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí kò ní òye; olúkúlùkù ń yà sọ́nà ara rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.