Isaiah 56:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé, “Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.” Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé, “Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti kò si jẹ ki ọmọ alejò ti o ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Oluwa sọ, wipe; Oluwa ti yà mi kuro ninu awọn enia rẹ̀ patapata: bẹ̃ni kò jẹ ki ìwẹ̀fà wipe, Wò o, igi gbigbẹ ni mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ OLÚWA sọ wí pé, “OLÚWA yóò yà mí ṣọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti kí ìwẹ̀fà kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”