Isaiah 56:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi, n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi. Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi; nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Ọrẹ síṣun àti ẹbọ wọn ni a ó tẹ́wọ́gbà lóríi pẹpẹ mi; nítorí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀ èdè.”