Isaiah 57:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Olódodo ń ṣègbé, kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i. A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé, pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLODODO ṣegbe, kò si ẹniti o kà a si: a mu awọn alãnu kuro, kò si ẹniti nrò pe a mu olododo kuro ṣaju ibi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olódodo ṣègbé kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀; a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ, kò sì sí ẹni tó yé pé a ti mú àwọn olódodo lọ láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.