Isaiah 57:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà, sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.” Ò ń wá agbára kún agbára, nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ãrẹ̀ mu ọ ninu jijìn ọ̀na rẹ: iwọ kò wipe, Ireti kò si: ìye ọwọ́ rẹ ni iwọ ti ri; nitorina ni inu rẹ kò ṣe bajẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ baa yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípá bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ọ yín.