Isaiah 57:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ta ni ń já ọ láyà, tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́; tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi? Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́, ni o kò fi bẹ̀rù mi?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ̀ru tani mbà ọ ti o si nfòya, ti o nṣeke, ti iwọ kò si ranti mi tabi ki o kà a si? emi kò ha ti dakẹ ani lati igbãni wá, iwọ kò si bẹ̀ru mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù tí ẹ fi ń ṣèké sí mi, àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítoríi dídákẹ jẹ́ ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́ tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?