Isaiah 57:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí o bá kígbe, kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́. Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọ Afẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí, ni yóo ni ilẹ̀ náà, òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba kigbe, jẹ ki awọn ẹgbẹ rẹ ki o gbà ọ; ṣugbọn ẹfũfu ni yio gbá gbogbo wọn lọ; emi yio mu wọn kuro: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹ rẹ̀ le mi yio ni ilẹ na, yio si jogun oke mimọ́ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín! Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ, èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ náà yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”