Isaiah 57:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ, ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́: òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́, ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀. Láti sọ ọkàn wọn jí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Ẹni-giga, ati ẹniti a gbéga soke sọ, ti ngbe aiyeraiye, orukọ ẹniti ijẹ Mimọ́, emi ngbe ibi giga ati mimọ́, ati inu ẹniti o li ẹmi irobinujẹ on irẹlẹ pẹlu, lati mu ẹmi awọn onirẹlẹ sọji, ati lati mu ọkàn awọn oniròbinujẹ sọji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.