Isaiah 57:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí n kò ní máa jà títí ayé, tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo: nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde, Èmi ni mo dá èémí ìyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi kì yio jà titi lai, bẹ̃ni emi kì yio binu nigbagbogbo: nitori ẹmi iba daku niwaju mi, ati ẽmi ti emi ti dá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kì yóò fẹ̀ṣùn kan ni títí láé, tàbí kí n máa bínú ṣá á, nítorí nígbà náà ni ọkàn ọmọnìyàn yóò rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi èémí ọmọnìyàn tí mo ti dá.