Isaiah 57:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun, nítorí òkun kò lè sinmi, omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn enia buburu dabi okun ríru, nigbati kò le simi, eyiti omi rẹ̀ nsọ ẹrẹ ati ẽri soke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru òkun tí kò le è sinmi, tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.