Isaiah 57:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì, àwọn ni ẹ̀ ń sìn, àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí, àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí. Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lãrin okuta ọ̀bọrọ́ odo ni ipín rẹ, awọn, awọn ni ipín rẹ: ani awọn ni iwọ dà ẹbọ ọrẹ mimu si: ti iwọ si rú ẹbọ ọrẹ jijẹ. Emi ha le gbà itunu ninu wọnyi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ère tí ó wà ní àárin òkúta dídán wọ̀n n nì, nínú kòtò jínjìn ni ìpín in yín; àwọn, àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ oníhóró. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró?