Isaiah 57:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn. O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀. O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀, ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin ilẹkùn ati opó ilẹkun ni iwọ si ti gbe iranti rẹ soke: nitori iwọ ti fi ara rẹ hàn fun ẹlomiran dipò mi, iwọ si ti goke: iwọ ti sọ akete rẹ di nla, iwọ si ba wọn dá majẹmu; iwọ ti fẹ akete wọn nibiti iwọ ri i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí. Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sí bẹ́ẹ̀dì yín sílẹ̀, ẹ gun oríi rẹ̀ lọ, ẹ sì sí i sílẹ̀ gbagada; ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀dì wọn, ẹ̀yin sì ń wo ìhòòhò wọn.