Isaiah 57:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki, o kó ọpọlọpọ turari lọ, o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ si ti lọ tiwọ ti ikunra sọdọ ọba, iwọ si ti sọ õrùn didùn rẹ di pupọ, iwọ si ti rán awọn ikọ̀ rẹ lọ jina réré, iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ, ani si ipò okú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin lọ sí Mólẹ́kì pẹ̀lú òróró ólífì ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín. Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré; ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!