Isaiah 58:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹ bá ṣe làálàá láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ẹ sì wá ọ̀nà ìtẹ́lọ́rùn fún ẹni tí ìyà ń jẹ, ìmọ́lẹ̀ yín yóo tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn biribiri yín yóo dàbí ọ̀sán.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ ba fà ọkàn rẹ jade fun ẹniti ebi npa, ti o si tẹ́ ọkàn ti a npọ́n loju lọrùn, nigbana ni imọlẹ rẹ yio si là ninu okùnkun, ati okùnkun rẹ bi ọ̀san gangan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀ṣán-gangan.